Ezekiel 29

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Ejibiti

1 aNí ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. 3Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti
ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú Òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí
àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ
èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;
èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”
4Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ
èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ
gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,
àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
5Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù
ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:
ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko
a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.
Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó
àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.
6Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé Èmi ni Olúwa.

“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli.
7Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.

8“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: kéyèsi Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. 9Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.

“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; Èmi ni mo ṣe é,”
10Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún. 12Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.

13“ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí. 14Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀. 15Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. 16Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ”

Èrè Nebukadnessari

17Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18“Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn. 19Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀. 20Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

21“Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ìwo Israẹli ru jáde, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárín wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Ezekiel 30

Ìpohùnréré ẹkún fún Ejibiti

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Hu, kí o sì wí pé,
“Ó ṣe fún ọjọ́ náà!”
3Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí
àní ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí
Ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùùkuu ṣú dúdú,
àsìkò ìparun fún àwọn kèfèrí.
4Idà yóò wá sórí Ejibiti
ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kuṣi
Nígbà tí àwọn tí a pa yóò ṣubú ní Ejibiti
wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ
ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀.
5Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti.

6“ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí:

“ ‘Àwọn àlejò Ejibiti yóò ṣubú
agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà
láti Migdoli títí dé Siene,
wọn yóò ti ipa idà ṣubú nínú rẹ;
Olúwa Olódùmarè wí.
7Wọn yóò sì wà
lára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,
ìlú rẹ yóò sì wà
ní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.
8Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ejibiti
tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.
9“ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kuṣi tí ó wà nínú àlàáfíà. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Ejibiti: Kíyèsi i, ó dé.

10“ ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn
ènìyàn Ejibiti láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli.
11Òun àti àwọn ológun rẹ̀
ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè
ní a o mú wá láti pa ilẹ̀ náà run.
Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Ejibiti
ilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa.
12Èmi yóò mú kí àwọn odò Naili gbẹ
Èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn ènìyàn búburú:
láti ọwọ́ àwọn àjèjì ènìyàn
Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò.
Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

13“ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run
Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère gbígbẹ́ ni Memfisi.
Kò ní sí ọmọ-aládé mọ́ ní Ejibiti,
Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.
14Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro
èmi yóò fi iná sí Ṣoani
èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi.
15Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu
ìlú odi Ejibiti
èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò
16Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti
Pelusiumu yóò japoró ní ìrora
Ìjì líle yóò jà ní Tebesi
Memfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo
17Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Heliopolisi àti Bubasiti
yóò ti ipa idà ṣubú
wọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn
18Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesi
nígbà tí mo bá já àjàgà Ejibiti kúrò;
níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin
wọn yóò fi ìkùùkuu bò ó
àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.
19Nítorí náà Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Ejibiti,
wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”
20Ní ọjọ́ keje oṣù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 21“Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣẹ́ apá Farao ọba Ejibiti. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a kò sì ti di i si àárín igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú. 22Nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí Farao ọba Ejibiti. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀. 23Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Ejibiti ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀. 24Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Farao, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a sá ní àṣápa. 25Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli lé, ṣùgbọ́n apá Farao yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ ọba Babeli yóò sì fi idà náà kọlu Ejibiti. 26Èmi yóò fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Ezekiel 31

Òpépé igi Sedari ni Lebanoni

1Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹta ọdún kọkànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn, sọ fún Farao ọba Ejibiti àti sí ìjọ rẹ̀:

“ ‘Ta ní a le fiwé ọ ní ọláńlá?
3Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni
Lebanoni ní ìgbà kan rí,
pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà;
tí ó ga sókè,
òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
4Omi mú un dàgbàsókè:
orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè;
àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká,
ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.
5Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío
ju gbogbo igi orí pápá lọ;
ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i:
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn,
wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
6 bẸyẹ ojú ọ̀run
kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀
gbogbo ẹranko igbó
ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀;
gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá
ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀.
7Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́,
pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀,
nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀
sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.
8 cÀwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run
kò lè è bò ó mọ́lẹ̀;
tàbí kí àwọn igi junifa
ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀,
tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀,
kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run
tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀.
9Mo mú kí ó ní ẹwà
pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọpọ̀
tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Edeni
tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.
10“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí; Nítorí pé ó ga lọ sókè fíofío, tí ó sì gbé òkè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ, àti nítorí pé gíga rẹ mú kí ó gbéraga, 11Mo fi lé alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀. Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, 12àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárín àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìji rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀. 13Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó ṣubú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko igbó wà ní àárín ẹ̀ka rẹ̀. 14Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárín àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.

15“ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jíjìn náà; Mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lebanoni ní aṣọ, gbogbo igi igbó gbẹ dànù. 16Mo mú kí orílẹ̀-èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìsàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Edeni, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lebanoni, gbogbo igi tí ó ní omi dáradára ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀. 17Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ òjìji rẹ̀, àwọn àjèjì rẹ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa.

18“ ‘Èwo lára igi Edeni ní a lè fiwé ọ ní dídán àti ọláńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Edeni lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárín àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.

“ ‘Èyí yìí ní Farao àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Ezekiel 32

Ìpohùnréré ẹkún fún Farao

1Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Farao ọba Ejibiti kí o sì wí fún un:

“ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàrín àwọn
orílẹ̀-èdè náà;
ìwọ dàbí ohun ẹ̀mí búburú inú àwọn omi okun to ń lọ
káàkiri inú àwọn odò rẹ,
ìwọ fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ omi
láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀.
3“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn
èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́
wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi.
4Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀
èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba.
Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe
àtìpó ní orí rẹ.
Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi
ìwọra gbé ara wọn lórí rẹ.
5Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí
àwọn òkè gíga
ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún
àwọn àárín àwọn òkè gíga
6Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà
gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga,
àwọn àlàfo jíjìn ní wọn yóò kún fún ẹran-ara rẹ.
7Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé
àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;
èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn
òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀
8Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run
ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ;
èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ,
ni Olúwa Olódùmarè wí
9Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú
nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ
kò í tí ì mọ̀.
10Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́,
àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún
ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ,
nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn
Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ
ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì
ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.
11“ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Idà ọba Babeli
yóò wá sí orí rẹ,
12Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó
tí ipa idà àwọn alágbára ènìyàn ṣubú
àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú jùlọ.
Wọn yóò tú ìgbéraga Ejibiti ká,
gbogbo ìjọ rẹ ní a yóò dá ojú wọn bolẹ̀.
13Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun
ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi
kì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀
ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni ẹrọ̀fọ̀.
14Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò
kí àwọn odò rẹ̀ kí o sàn bí epo,
ni Olúwa Olódùmarè wí.
15Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro,
tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò.
Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀,
nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
16“Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

17Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá: 18“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún lórí Ejibiti kí o sì ránṣẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò. 19Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ní ojúrere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárín àwọn aláìkọlà náà.’ 20Wọn yóò ṣubú láàrín àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Ejibiti kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀. 21Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Ejibiti àti àwọn àlejò rẹ̀, ‘Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.’

22“Asiria wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagunjagun rẹ̀; àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. 23Isà òkú wọn wà ní ibi tí ó jinlẹ̀ gan an nínú kòtò. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè ní a pa, tí ó ti ipa idà ṣubú.

24“Elamu wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò. 25A ṣe ibùsùn fún un láàrín àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa. Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò; a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa.

26“Meṣeki àti Tubali wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ogun wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù tiwọn tàn ká ilẹ̀ alààyè. 27Wọn kì yóò sì dùbúlẹ̀ ti àwọn tí ó ṣubú nínú àwọn aláìkọlà, tí wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun wọn, wọ́n tí fi idà wọn rọ orí wọn. Ṣùgbọ́n àìṣedéédéé wọn yóò wà ní orí egungun wọn—bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀rù àwọn alágbára ní ilẹ̀ alààyè.

28“Ìwọ náà, Farao, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàrín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.

29“Edomu wà níbẹ̀, àwọn ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin ọba; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò.

30“Gbogbo àwọn ọmọ-aládé ilẹ̀ àríwá àti gbogbo àwọn ará Sidoni wà níbẹ̀; wọn lọ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a pa ní ìtìjú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ṣe okùnfà ẹ̀rù pẹ̀lú agbára wọn. Wọn sùn ní àìkọlà pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn sì ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.

31“Farao, òun àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ yóò rí wọn, a yóò sì tù ú nínú nítorí gbogbo ogun rẹ̀ tí a fi idà pa, ní Olúwa Olódùmarè wí. 32Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè, Farao àti gbogbo ogun rẹ̀ ni a yóò tẹ́ sí àárín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Copyright information for YorBMYO